Hymn 099 – EYIN egbe Serafu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EYIN egbe Serafu" (C&S Hymn #099, Yoruba). 1. ẸYIN Ẹgbẹ Séráfù, Ati Ẹgbẹ Kérúbù, Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun, T'o d'ẹmi wa si…
1. ẸYIN Ẹgbẹ Séráfù, Ati Ẹgbẹ Kérúbù, Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun, T'o d'ẹmi wa si d'oni. Emi ko le sai sọpẹ (2ce) Ore t'Ọlọrun se fun mi, Emi ko le sai sọpẹ. 2. Lootọ l'esu gbogun, Sugbọn ko le sẹgun, Lagbara Mẹtalọkan wa, Awa yoo bori rẹ. 3. Ẹlomiran ti ku, Ẹlomiran w'ẹwọn, Ẹlomiran ń rin ni ilẹ, Ti moto ti tẹ pa. 4. Ọpẹ ni f'Ọlọrun, F'anu Rẹ l'ori wa, O gbọ tirẹ, O gbọ temi, Ogo ni f'Ọlọrun. 5. Ọlọrun alaanu, Siju aanu wo wa, Jọwọ pese fun aini wa K'ile r'oju fun wa. 6. F'ilera f'alaisan, Jesu Olugbala; Jẹki awọn alaisan, Ri 'wosan lọdọ Rẹ. 7. Mu ileri Rẹ sẹ, Jehovah Tabbikubb, K'awọn afọju le riran, K'alailera k'o san. 8. Ọpọ ti sako lọ, Wọn ko si mọna mọ, Ẹlomiran j'asiwaju, Sugbọn o fa s'ẹhin. 9. Jehovah-Jire wa, Pese fun aini wa, Pese ọmọ f'awọn agan, Jẹk'a ri 'bukun gba. 10. Ọlọrun alaanu, Dariji ẹda Rẹ; Mase f'ẹsẹ bi arayé Jẹki ojo k'o rọ. 11. F'ibukun Rẹ f'Ọba, At'awọn Igbimọ, F'alafia fun ilu wa, K'a ma rogun adaja. 12. Ẹ f'ogo fun Baba Ẹ f'ogo fun Ọmọ Ẹ f'ogo fun Ẹmi Mimọ, Mẹtalọkan lailai. Emi ko le sai sọpẹ (2ce) Ore t'Ọlọrun se fun mi, Emi ko le sai sọpẹ. AMIN
Hymn 099 – EYIN egbe Serafu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia