Hymn 100 – NI TOOTO, ara ni tooto o | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "NI TOOTO, ara ni tooto o" (C&S Hymn #100, Yoruba). 1. NI TOOTỌ, ara ni tootọ o, Baba wa seun fun wa ka f'iyin fun, Ọpẹ…
1. NI TOOTỌ, ara ni tootọ o, Baba wa seun fun wa ka f'iyin fun, Ọpẹ lo yẹ Ọ Ayisa-Osu, Dakun wa gb'ọpẹ wa gba 'yin wa. Ọba toto! Kabiyesi! Awa wolẹ, o awa juba Rẹ o, Ẹrintunde a mu 'yin wa o, Wa jẹ ki ọpẹ wa goke lọ. 2. Ẹyin ti a dasi ẹ juba Rẹ o, Ẹ juba Oluwa to ń pa wa mọ, Ẹgbẹgbẹrun subu l'ọtun l'osi, Sugbọn Oluwa pa wa mọ! 3. Ọpọ ọmọ ayé to ti kọja o, Anu lo fi sọ wa titi d'oni, OBIRITI l'Oluwa wa, O ń dari ibi kuro lọdọ wa. 4. Ogo, Ọla, Ọpẹ lo yẹ fun Ọ o, Jẹ k'a le yin Ọ o l'oke ọrun, 'Gba ba s'isẹ l'ayé yi Oluwa, Ka le ba Maleka k'Alleluyah. Ọba toto! Kabiyesi! Awa wolẹ, o awa juba Rẹ o, Ẹrintunde a mu 'yin wa o, Wa jẹ ki ọpẹ wa goke lọ. AMIN
Hymn 100 – NI TOOTO, ara ni tooto o | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia