Hymn 098 – EYIN egbe Serafu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EYIN egbe Serafu" (C&S Hymn #098, Yoruba). 1. ẸYIN ẹgbẹ Séráfù Wa fi ayọ yin han Ẹ jumọ kọ orin didun, Fun 'sẹ 'yanu…

Hymn 098 – EYIN egbe Serafu | C&S Yoruba Hymnary
1. ẸYIN ẹgbẹ Séráfù Wa fi ayọ yin han Ẹ jumọ kọ orin didun, Fun 'sẹ 'yanu to se fun wa, Ti ko jẹ ka sọnu kuro ni ọna rẹ A ń yan lọ si Sion, Sion to dara julọ, A ń yan goke lọ si Sion, Ilu Ọlọrun wa. 2. Baba Aladura, F'ọpẹ fun Ọlọrun, T'o mu O bori awọn ọta, Ti ko jẹ ki ọta yọ ọ, To fi ọ se ori, Yio fi o se d'opin. 3. Ẹyin Ẹgbẹ Akọrin, Ẹ fi ayọ yin han; Fun Majẹmu Rẹ ti ko yẹ, Ni arin Ẹgbẹ Séráfù, To musẹ di oni, Ati ayé ti mbọ. 4. Eniyan le ma kẹgan, Wọn si le ma sata; Awọn ti ko m'Ọlọrun wa, Sugbọn awa Ẹgbẹ Kérúbù, A si m'ẹni t'a ń sin, Yio si fun wa lere 5. Kérúbù Séráfù, Ẹ mura sis'ẹmi, Ẹyin yoo sisẹ naa dopin, Ẹ o si ri Olugbala, L'aye mimọ loke, Ati l'ọrun pẹlu. AMIN

Hymn 098 – EYIN egbe Serafu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia