Hymn 97 – OLORUN Eleda t'o da'jo Seraf | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN Eleda t'o da'jo Seraf" (C&S Hymn #97, Yoruba). 1. ỌLỌRUN Ẹlẹda t'o da'jọ Seraf' Ati Kérúbù s'orilẹ ede ayé,…

Hymn 97 – OLORUN Eleda t'o da'jo Seraf | C&S Yoruba Hymnary
1. ỌLỌRUN Ẹlẹda t'o da'jọ Seraf' Ati Kérúbù s'orilẹ ede ayé, Lat'ọwọ Jesu Olugbala ọwọn; Awa n yin orukọ Rẹ logo A! ẹ ku ayọ, ẹ ku ayọ ) Ijọ Séráfù )2ce A! ẹ ku ayọ, ẹ ku ayọ ) Ijọ Kérúbù. ) 2. Nibo l'awọn ayanfẹ Ọlọrun wa? Ẹ wa gbọ ohun Olusọ-aguntan yi: Ẹ ronupiwada, ẹ wa w'ọkọ naa; Igbala na ku si atẹlẹwọ. 3. Ẹgbẹ Kérúbù dupẹ lọwọ Ọlọrun, Tẹsiwaju ninu ogun ẹmi jija, Ẹ fẹrẹ gbo'hun Oluwa Jesu, Wi pé, o seun, ọmọ rere 4. Ẹyin ti n kọja lọ ya sọdọ Jesu, Lati gb'ore-ọfẹ n'nu Ijọ yi, Mase kẹgan ọkọ igbala 'kẹhin, T'Ọlọrun Mẹtalọkan fun wa. 5. Jesu Oluwa mbọ wa j'Ọba layé, Larin Ẹgbẹ Kérúbù ati Séráfù, Ẹgbẹrun ọdun ni 'jỌba Rẹ ninu, Ijọ Mimọ at'oke wa yi. 6. Jesu Kristi Oluwa Ọba Ogo, L'ọpa iye ainipẹkun wa lọwọ Rẹ; Yoo ko gbogbo awọn t'o gbagbọ lọ, Siwaju itẹ Baba l'oke. AMIN

Hymn 97 – OLORUN Eleda t'o da'jo Seraf | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia