Hymn 905 – IWO ha ni idakoro t’o daju | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "IWO ha ni idakoro t’o daju" (C&S Hymn #905, Yoruba). 1. IWO ha ni idakoro t’o daju Ninu irumi at’iji aye Nigba ti ikun…
1. IWO ha ni idakoro t’o daju Ninu irumi at’iji aye Nigba ti ikun omi ba dide Idakoro re ha le duro. Egbe: ldakoro n be fun okan wa B’o ti wu ki iji naa le to Jesu l’Apata ti ko le ye Lor’Apata ife Re l'a n duro. 2. A ti gunle s’ebute isinmi Ko s’ewu a n be lowo Oluwa Dakoro t’O ti s’inu okan mi Yoo duro b’o ti wu k’iji le to. Egbe: ldakoro n be fun okan wa... 3. Yoo duro sinsin b’eru tile de Awon ota wa ni oju yoo ti Ko si igbi t‘o le ba wa l’eru Awa n'idakoro t'o daju. Egbe: ldakoro n be fun okan wa... 4. Yoo duro girl titi de opin Titi iku yoo ti p’oju wa de Looro ajinde ko si Ie kuna Oun n‘idakoro ireti wa. Egbe: ldakoro n be fun okan wa... 5. ‘Gba t'oju wa ba r'ewa ogo Re Ni ebute ti a fi wura ko A o duro lor'idakoro wa Gbogbo iji yoo re wa koja. Egbe: ldakoro n be fun okan wa B’o ti wu ki iji naa le to Jesu l’Apata ti ko le ye Lor’Apata ife Re l'a n duro. Amin
Hymn 905 – IWO ha ni idakoro t’o daju | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia