Hymn 904 – WO awon t'o wo ‘so ala | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "WO awon t'o wo ‘so ala" (C&S Hymn #904, Yoruba). 1. WO awon t'o wo ‘so ala Won duro leti odo Won k‘eyin s'aye at‘esu…
1. WO awon t'o wo ‘so ala Won duro leti odo Won k‘eyin s'aye at‘esu Won ntele Atebomi Won si nreti Lati se ase Jesu. 2. Wo bi won ti duro l'eru Sugbon pelu ireti Won mo pe Olugbala won L‘O pase odo lilo Jordan tutu Sugbon igbagbo gbona. 3. Si wo awon arakunrin Egbon won ninu Jesu Wo bi won ti na’ wo ife Won sa ti dabi won ri, Nisisiyi Won ny‘ayo idariji. 4. Lo, tele Olugbala yin E f'oju igbagbo ri A! orun si, Emi Baba Si nke lat‘oke wipe Awon wonyi Ni ayanfe omo Mi. Amin
Hymn 904 – WO awon t'o wo ‘so ala | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia