Hymn 009 – K'A to sun, olugbala wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "K'A to sun, olugbala wa" (C&S Hymn #009, Yoruba). 1. K'A to sun, Olugbala wa, Fun wa n'ibukun alẹ; A jẹwọ ẹsẹ fun Ọ,…
1. K'A to sun, Olugbala wa, Fun wa n'ibukun alẹ; A jẹwọ ẹsẹ fun Ọ, Iwọ lo le gba wa la. 2. B'ilẹ tilẹ su dudu, Okun ko le se wa mọ; Iwọ ẹni ti ki sàárẹ, N sọ awọn eniyan Rẹ. 3. B' iparun tilẹ yi wa ka, Ti ọfa ń fo wa kọja, mf Awọn Angẹli yi wa ka, Awa o wa l'ailewu. 4. Sugbọn b'iku ba ji wa pa, Ti busun wa d'iboji, mf Jẹ k'ilẹ mọ wa sọdọ Rẹ, L'ayọ at' alafia. 5. N' irẹlẹ awa f'ara wa, Sabẹ abo Rẹ, Baba, Jesu, 'Wọ t'o sun bi awa, Se orun wa bi Tirẹ. 6. Ẹmi Mimọ radọ bo wa, Tan 'mọlẹ s'okunkun wa, Tit'awa o fi ri ọjọ, Imọle ayeraye. AMIN
Hymn 009 – K'A to sun, olugbala wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia