Hymn 010 – L'OJU ale, 'gbat'orun wo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "L'OJU ale, 'gbat'orun wo" (C&S Hymn #010, Yoruba). 1. L'OJU alẹ, 'gbat'orun wọ, Wọn gbe abirun w'ọdọ Rẹ; Oniruru ni…
1. L'OJU alẹ, 'gbat'orun wọ, Wọn gbe abirun w'ọdọ Rẹ; Oniruru ni aisan wọn, Sugbọn wọn f'ayọ lọ'le wọn. 2. mi Jesu a de lọj'alẹ yi, A sunmọ t'awa t'arun wa; cr Bi a ko tilẹ le ri Ọ, Sugbọn a mọ p'O sunmọ wa 3. Olugbala, wo osi wa, Omii ko san, ‘mii banujẹ, Omii ko ni ifẹ si Ọ, Ifẹ ẹlomii si tutu. 4. Omii mọ pe asan l'aye, Bẹni wọn ko f'aye silẹ; Omii l'ore ti ko se're, Bẹni wọn ko fi Ọ s'ọrẹ. 5. Ko s'ọkan ninu wa t'o pe, Gbogbo wa si ni ẹlẹsẹ, Awọn t'o si n sin Ọ totọ, Mọ ara wọn ni alaipe. 6. Sugbọn Jesu Olugbala, Ẹni bi awa ni iwọ 'se; 'Wọ ti ri 'danwo bi awa, 'Wọ si ti mọ ailera wa. 7. Agbar'ọwọ Rẹ wa sibẹ, Ọrọ Rẹ si ni Agbara, Gbọ adura alẹ wa yi, Ni aanu, wo gbogbo wa san. AMIN
Hymn 010 – L'OJU ale, 'gbat'orun wo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia