Hymn 008 – JESU, bukun wa k'a to lo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JESU, bukun wa k'a to lo" (C&S Hymn #008, Yoruba). 1. JESU, bukun wa k'a to lọ; Gbin ọrọ Rẹ si ọkan wa; K'o si mu…

Hymn 008 – JESU, bukun wa k'a to lo | C&S Yoruba Hymnary
1. JESU, bukun wa k'a to lọ; Gbin ọrọ Rẹ si ọkan wa; K'o si mu k'ifẹ gbigbona, Kun ọkan ilọwọwọ wa, Nigba iye at'iku wa, Jesu, jare se 'mọlẹ wa. 2. Ilẹ ti su, orun ti wọ, 'Wọ si ti siro iwa wa, Diẹ n'isẹgun wa loni, Isubu wa lo papọju: Nigba iye at'iku wa, &c 3. Jesu dariji wa: fun wa L'ayọ ati ẹru mimọ, At'ọkan ti ko l'abawọn K'a ba le jọ Ọ l'ajọtan: Nigba iye at'iku wa, &c. 4. Lala dun 'tor'Iwọ se ri, Aniyan fẹrẹ, O se ri: Ma jẹ k'a gbọ t'ara nikan K'a ma bọ sinu idanwo, Nigba iye at'iku wa, &c. 5. A mbẹ Ọ f'awọn alaini, F'ẹlẹsẹ at'awọn t'a fẹ, Jẹ ki anu Rẹ mu wa yọ, 'Wọ Jesu, l'ohun gbogbo wa. Nigba iye at'iku wa, &c. 6. Jesu, bukun wa, ilẹ su; Tikalarẹ wa ba wa gbe, Angẹl' rere ń sọ ile wa; A tun f'ọjọ kan sunmọ Ọ Nigba iye at'iku wa, &c. AMIN

Hymn 008 – JESU, bukun wa k'a to lo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia