Hymn 007 – JESU oorun ododo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU oorun ododo" (C&S Hymn #007, Yoruba). 1. JESU oorun ododo, Iwọ imọle ifẹ; Gbat'imọlẹ owurọ, Ba n t'ila oorun tan…
1. JESU oorun ododo, Iwọ imọle ifẹ; Gbat'imọlẹ owurọ, Ba n t'ila oorun tan wa, Tan'mọlẹ ododo Rẹ Yi wa ka. 2. Gẹgẹ bi iri ti ń sẹ, Sori eweko gbogbo, K'Ẹmi ore' ọfẹ Rẹ Sọ ọkan wa di ọtun; Rọ ojo ibukun Rẹ Sori wa 3. B' imọlẹ orun ti n ran, K' imọlẹ ifẹ Tirẹ, Si ma gbona l'ọkan wa; K'o si mu wa l'ara ya, Ka le ma fayọ sin Ọ L'aye wa. 4. Amọna, ireti wa, Ma fi wa silẹ titi, Fi wa sabẹ isọ Rẹ Titi opin ẹmi wa. Sin wa la ajo wa ja S'ile wa. 5. Pa wa mọ n'nu ifẹ Rẹ, Lọjọ aye wa gbogbo. Si mu wa bori iku, Mu wa de'le ayọ naa, Ka le b'awọn mimọ gba isinmi AMIN
Hymn 007 – JESU oorun ododo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia