Hymn 006 – IWO Imole okan mi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "IWO Imole okan mi" (C&S Hymn #006, Yoruba). 1. IWỌ Imọlẹ ọkan mi, Ni ọdọ Rẹ òru kò si; Ki kuuku ayé ma bo Ọ, Kuro…

Hymn 006 – IWO Imole okan mi | C&S Yoruba Hymnary
1. IWỌ Imọlẹ ọkan mi, Ni ọdọ Rẹ òru kò si; Ki kuuku ayé ma bo Ọ, Kuro l'oju iransẹ Rẹ. 2. Nigba t'orun alẹ didun; Ba n pa ipenpeju mi de, K'ero mi jẹ lati sinmi, Lai l'aya Olugbala mi. 3. Ba mi gbe l'oorọ tit'alẹ, Laisi Rẹ emi ko le wa, Ba mi gbe gbat'ilẹ ba ń su; Laisi Rẹ, emi ko le ku. 4. Bi otosi ọmọ Rẹ kan, Ba tapa s'ọrọ Rẹ loni, Oluwa, sisẹ ore Rẹ, Ma jẹ k'o sun ninu ẹsẹ. 5. Bukun fun awọn alaisan, Pese fun awọn talaka; di K'orun alawe l'alẹ yi, Dabi orun ọmọ tuntun. 6. Sure fun wa nigba t'a ji, K'a to m'ohun ayé yi se, f Titi awa o de 'bitẹ, T'a o si de ijọba Rẹ. AMIN

Hymn 006 – IWO Imole okan mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia