Hymn 890 – TAN ihin na kale, jakejado aiye | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "TAN ihin na kale, jakejado aiye" (C&S Hymn #890, Yoruba). 1. TAN ihin na kale, jakejado aiye K'awon ti eru npa Mo pe…
1. TAN ihin na kale, jakejado aiye K'awon ti eru npa Mo pe igbala de K‘awon t’ise ti Krist’ So ihin ayo na. Egbe: Olutunu ti de, Olutunu ti de Emi Iat’ oke wa, ileri Baba wa Tan ihin na kale, jakejado aiye Olutunu ti de. 2. Oba awon oba, wa f 'iwosan fun wa O wa ja ide wa, O mu igbala wa K‘olukuluku wa, korin isegun pe. Egbe: Olutunu ti de... 3. lfe iyanu nla, a! mba rohin na Fun gbogbo enia, ehun or‘ofe Re Emi omo egbe, di omo igbala. Egbe: Olutunu ti de... 4. Gbe orin ‘yin soke s'olurapada wa K‘awon mimo l‘oke Jumo ba wa gberin Yin ife re titi, ife ti ko le ku. Egbe: Olutunu ti de, Olutunu ti de Emi Iat’ oke wa, ileri Baba wa Tan ihin na kale, jakejado aiye Olutunu ti de. Amin
Hymn 890 – TAN ihin na kale, jakejado aiye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia