Hymn xvii – E wa s'apakan, k'e sinmi die | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E wa s'apakan, k'e sinmi die" (C&S Hymn #xvii, Yoruba). Ẹ wa s'apakan, k'ẹ sinmi diẹ. Mo mọ arẹ ati wahala yin, Ẹ nu…
Ẹ wa s'apakan, k'ẹ sinmi diẹ. Mo mọ arẹ ati wahala yin, Ẹ nu òógun oju yin nù kuro, K'ẹ tun gb'agbara n'nu agbara mi. Ẹ takete s'ohun adun aye, Ẹ wa fun idapọ t'aye ko mọ, Ẹnikan wa lọdọ Mi oun Baba, Lọdọ Mi oun Baba ẹgbẹ yin kun. Ẹ wa sọ gbogb'ohun t'ẹ se fun mi, So t'isẹgun ati t'isubu yin. Mo mọ b'isẹ ẹmi ti soro to, Ade t'o dara t'on t'omije ni. Ẹ wa sinmi, ajo naa jin pupọ, Aarẹ o mu yin, ẹ o ku l'ọna Ounjẹ iye wa nihin, ẹ wa jẹ, Nihin l'omi iye wa, ẹ wa mu. Jade lọtun lat'ọdọ Oluwa, Ẹ pada lọ sisẹ titi sulẹ: Ẹ ko padanu wakati t'ẹ lo F'ẹkọ mi si, at'isinmi ọrun. AMIN
Hymn xvii – E wa s'apakan, k'e sinmi die | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia