Hymn 087 – OPE lo ye f'Olugbala | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OPE lo ye f'Olugbala" (C&S Hymn #087, Yoruba). 1. ỌPẸ lo yẹ f'Olugbala, Iyin fun Mẹtalọkan; T'o da wa si d'ọjọ oni, A…
1. ỌPẸ lo yẹ f'Olugbala, Iyin fun Mẹtalọkan; T'o da wa si d'ọjọ oni, A f'ogo f'orukọ Rẹ. Kọrin Ogo, Alleluya, Orin ogo la o kọ, Kọrin Ogo, Alleluya, Kọ Hossanah s'Ọba wa. 2. Mẹtalọkan Ọba Ogo, Baba fun wa l'agbara, F'awọn asaju n'isẹgun, Fun wọn l'ọgbọn at'oye. 3. Ọbangiji Ọba Ogo, Ranti Ẹgbẹ Aladaura; Fun wọn l'agbara at'ifẹ Ko wọn l'adura t'ọrun. 4. Jehovah-Nissi Ọba wa, Saanu f'Ẹgbẹ Séráfù; F'isẹgun f'Ẹgbẹ Kérúbù, Se wa gẹgẹ bi t'ọrun. 5. Awọn ti ko ri'se yoo ri, Agan a f'ọwọ s'osun; Ọlọmọ ko ni padanu Alaisan yoo dide. 6. Gbọ tiwa Baba wa ọrun, Ranti Ẹgbẹ idalẹ; Fun wọn l'agbara at'ipa, Fun gbogbo wa n'isẹgun. 7. Jehovah Shammah Ọba wa, Gba t'o ba d'ọjọ ikẹyin; Mu wa d'agbala itura, JAH mu wa de'tẹ Ogo. AMIN
Hymn 087 – OPE lo ye f'Olugbala | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia