Hymn 88 – A YIN Ọba Ogo, Oun ni Ọlọrun, | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "A YIN Ọba Ogo, Oun ni Ọlọrun," (C&S Hymn #88, Yoruba). 1. A YIN Ọba Ogo, Oun ni Ọlọrun, Ẹ yin fun'sẹ 'yanu ti O se fun…
1. A YIN Ọba Ogo, Oun ni Ọlọrun, Ẹ yin fun'sẹ 'yanu ti O se fun wa, Fun sisọ t'o n sọ wa ni ọjọ gbogbo, Fun ọwọ ina ati awọsanma. Ẹyin Angẹli didan fi harpu wura yin, Ẹyin Ogo ọrun t'ẹ n ri oju Rẹ, Yika gbogbo ayé titi? Lai n'isẹ Rẹ yo ma yin Fi ibukun f'Oluwa iwọ ọkan mi. 2. Ẹ yin fun igbala to fun wa l'ọfẹ, Ẹ yin fun Orisun to le wẹ wa mọ; Ẹ yin fun ore ati itọju Rẹ, Ẹ yin pẹlu pe O n gbọ adura wa. 3. Ẹ yin fun idanwo, ti o n ran si wa, Lati fi s'okunfa wa s'ọdọ 'ra Rẹ; Ẹ yin fun igbagbọ lati ma sẹgun, Ẹ yin fun 'leri ilu ọrun rere. AMIN
Hymn 88 – A YIN Ọba Ogo, Oun ni Ọlọrun, | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia