Hymn 086 – OLUWA ọrun oun ayé, | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA ọrun oun ayé," (C&S Hymn #086, Yoruba). 1. OLUWA ọrun oun ayé, Wọ n'iyin at'ọpẹ yẹ fun; Bawo l'a ba ti fẹ Ọ to?…

Hymn 086 – OLUWA ọrun oun ayé, | C&S Yoruba Hymnary
1. OLUWA ọrun oun ayé, Wọ n'iyin at'ọpẹ yẹ fun; Bawo l'a ba ti fẹ Ọ to? Onibu-ọrẹ. 2. Orun ti ń ran at'afẹfẹ, Gbogbo eweko ń sọ'fẹ Rẹ; 'Wọ l'O ń mu irugbin dara, Onibu-ọrẹ. 3. Fun ara lile wa gbogbo, Fun gbogbo ibukun ayé; Awa yin Ọ, a si dupẹ, Onibu-ọrẹ. 4. O ko du wa ni ọmọ Rẹ, O fi fun ayé ẹsẹ wa; O si f'ẹbun gbogbo pẹlu, Onibu-ọrẹ. 5. O fun wa l'Ẹmi Mimọ Rẹ, Ẹmi iye at'agbara; O rọjo ẹkun 'bukun Rẹ Le wa lori. 6. Fun idariji ẹsẹ wa, Ati fun ireti ọrun; Ki l'ohun t'a ba fi fun Ọ? Onibu-ọrẹ. 7. Owo, ti a ń na, ofo ni, Sugbọn eyi t'a fi fun Ọ; O jẹ isura tit'ayé, Onibu-ọrẹ. 8. Ohun t'a bun Ọ Oluwa, 'Wọ o san le e pada fun wa; Layọ l'a o ta Ọ lọrẹ, Onibu-ọrẹ. 9. Ni ọdọ Rẹ l'a ti san wa, Ọlọrun Olodumare; Jẹ k'a le ba Ọ gbe titi Onibu-ọrẹ. AMIN

Hymn 086 – OLUWA ọrun oun ayé, | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia