Hymn 085 – Ẹ GBE ohun ayọ at'iyin ga, Alleluyah! | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Ẹ GBE ohun ayọ at'iyin ga, Alleluyah!" (C&S Hymn #085, Yoruba). 1. Ẹ GBE ohun ayọ at'iyin ga, Alleluyah! Orin ogo Ọba…
1. Ẹ GBE ohun ayọ at'iyin ga, Alleluyah! Orin ogo Ọba nla l'awọn ti A rapada y'o ma kọ: Alleluya! Alleluya! 2. Awọn ẹgbẹ akọrin ọrun, Wọn a gberin naa yika ọrun, Alleluya! Alleluya! 3. Awọn ti ń rin gbẹfẹ kiri ni Paradise, Awọn ẹni 'bukun ni, wọn a ma kọ orin wi pé, Alleluya! Alleluya! 4. Awọn 'rawọ ti n tan mọlẹ wọn, Ati gbogbo awọn ẹgbẹ irawọ da ohun wọn lu wi pé, Alleluya! Alleluya! 5. Ẹyin sanmọ t'o n wọ si lọ, at'ẹyin ẹfufu, Ẹyin ara t'o n san wa, ẹyin manamana ti o n kọ mana; Ẹ fi ayọ gberin, Alleluya! 6. Ẹyin omi, at'igbi okun, ẹyin ojo, at'otutu, Ẹyin ojo dida ra gbogbo, Ẹyin igboro at' igbo, Ẹ gberin naa, Alleluya! 7. mf Ẹyin oniruru ẹyẹ, ẹ kọrin iyin Ẹlẹda yin pe, Alleluya! Alleluya! 8. Ẹyin ẹranko igbẹ, ẹ d'o hun yin lu, Ẹ si kọrin iyin Ẹlẹda wi pé Alleluya! Alleluya! 9. Jẹ k'awọn oke k'o bu s'ayọ, Alleluya! K'awọn pẹtẹlẹ si gberin naa, Alleluya! 10. Ẹyin ọgbun omi kun, ẹ kọ wi pé, Alleluya! Ẹyin ilẹ gbigbẹ, ẹ dahun wi pé, Alleluya! 11. Ọlọrun t'O da ayé ni k'a f'orin yin; Alleluya! Alleluya! 12. Eyi l'orin ti Ọlọrun fẹ, Alleluya! Eyi l'orin ti Krist tika larẹ fẹ, Alleluya! 13. Nitori naa, tọkantọkan la'o fi kọrin, Alleluya! Awọn ọmọde wẹwẹwẹ y'o gba orin naa kọ wi pé Alleluya! 14. Ki gbogbo eniyan ki o kọ Alleluya si Ọlọrun; Alleluya titi ayé, Fun Ọmọ oun Ẹmi Mimọ. 15. Ogo ni f'Ologo Mẹta Alleluya! Alleluya! Alleluya! AMIN
Hymn 085 – Ẹ GBE ohun ayọ at'iyin ga, Alleluyah! | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia