Hymn 084 – EYIN Angel to wa l'orun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EYIN Angel to wa l'orun" (C&S Hymn #084, Yoruba). 1. ẸYIN Angẹl to wa l'ọrun, Ẹ fi iyin fun Baba; Fun‘jọ to da silẹ…
1. ẸYIN Angẹl to wa l'ọrun, Ẹ fi iyin fun Baba; Fun‘jọ to da silẹ layé, Fun igbala ẹmi, O yẹ ki inu wa ko dun, Ki awa ki o si ma yọ! Fun iranti iku Jesu, Lori Agbelebu. A pa lasẹ l'agbala ọrun, Pe k'Ẹgbẹ yi ma bi si; A pa lasẹ l'agbala ọrun, Pe ko si ma rẹ si; Titi gbogbo ifọju ọkan, Yio o fi tan layé; T'iku Jesu Oluwa wa, Ko ni jẹ asan mọ. 2. Kérúbù ati Séráfù, Ẹ fi iyin fun Baba; Ti o da Ẹgbẹ yi silẹ, Pe k'a le ri igbala, 'Tori na, ẹ jẹ k'a mura, Lati sare ije yi, Bi a ba foriti d'opin, Iye y'o jẹ tiwa. 3. Gbogbo isẹ wa ti a n se, Gbogbo iwa ti a n hu, Gbogbo ọrọ wa ti a n sọ, Ẹ jẹ k'a ma sọra, Nitori Oluwa yoo mu, Gbogbo 'sẹ wa si 'dajọ, Ati gbogbo ohun 'kọkọ, Ire tabi ibi. 4. Awa ni imọlẹ ayé, Lati le okunkun lọ, Ilu ta tẹ sori oke, A ko le fara sin; Awa si ni iyọ ayé, Ti a o mu ayé dun, Sugbọn b'iyọ ba di obu, Bawo ni yoo se dun? 5. Ọpẹ lo yẹ Olugbala, Fun ifẹ to ni si wa; Ti o pe wa si Ẹgbẹ yi, Ọkọ 'gbala 'kẹhin; Ogo, ọla at'agbara, Ọla nla at'ipa, Ni fun Baba, Ọmọ, Ẹmi, Mẹtalọkan lailai. AMIN
Hymn 084 – EYIN Angel to wa l'orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia