Hymn 083 – A DUPE lowo Olorun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "A DUPE lowo Olorun" (C&S Hymn #083, Yoruba). 1. A DUPẸ lọwọ Ọlọrun T'O da wa si d'oni; T'o jẹ k'ẹmi tun ẹmi ri, Ogo…
1. A DUPẸ lọwọ Ọlọrun T'O da wa si d'oni; T'o jẹ k'ẹmi tun ẹmi ri, Ogo f'orukọ Rẹ. A dupẹ lọwọ Ọlọrun, T'o da ẹmi wa si d'oni; T'o jẹ k'ẹmi tun ẹmi ri, Ogo f'orukọ Rẹ. 2. Isẹ pọ n'ilu Osogbo, T'Ilesa ko ni sọ; Ẹgbẹ Ondo ti mura tan, Lati gbe Jesu ga. 3. Ẹgbẹ Eko damure yin, Lati besu jagun; Oko pọn pupọ n'ilu Oke, Tani yoo lọ ka? 4. A ki Baba Aladura, O ku afojuba; Olori ti jagun fun Jesu, O si sẹgun Esu. 5. Orin Halle, Halleluya, L'awa y'o kọ l'ọrun; Nigba t'a ba r'Olugbala, Ni ori itẹ Rẹ. AMIN
Hymn 083 – A DUPE lowo Olorun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia