Hymn 082 – EGBE Kerubu a de, lati yin Baba | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EGBE Kerubu a de, lati yin Baba" (C&S Hymn #082, Yoruba). 1. ẸGBẸ Kérúbù a de, lati yin Baba; Gbogbo agbayé ẹ wa o, ka…

Hymn 082 – EGBE Kerubu a de, lati yin Baba | C&S Yoruba Hymnary
1. ẸGBẸ Kérúbù a de, lati yin Baba; Gbogbo agbayé ẹ wa o, ka jọ yin Baba. 2. Ẹgbẹ Séráfù a de, lati yin Baba, Tewe-tagba ẹ wa o, ka jọ yin Baba. 3. Igun mẹrẹrin ẹ wa, ka lọ yin Baba, Kérúbù pẹlu Séráfù, se wọn yin Baba. 4. Tọmọde tagba, ẹ wa fi'yin fun Baba, Kérúbù pẹlu Séráfù, awa yin Baba. 5. Jesu Olugbala, a de lati yin Baba, Jọwọ se 'ranti Kérúbù, pe wa ni Tirẹ. 6. Jesu Olugbala ko wa, jọwọ ko wa lọ, Ọdọ Baba wa loke, jọwọ ko wa lọ. 7. Jesu Olugbala, o se, o ko jẹ k'awa gbe, Igbekun t'esu di silẹ, ko jẹ k'awa gbe. 8. Ẹyin obinrin, ẹ rọju, ẹ rọju ẹ ma bohun bọ, Gbogbo ẹni dabi Hannah Baba o gbọ tirẹ. 9. Baba ranti arugbo, to wa ninu wa, K'ebi alẹ ma pa wọn, jọwọ ranti wọn. 10. Ẹmi Mimọ wa, jọwọ fi han ni, Ọrọ Mimọ Bibeli, jọwọ fi han ni. AMIN

Hymn 082 – EGBE Kerubu a de, lati yin Baba | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia