Hymn 081 – E YO nin'Oluwa, e yo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E YO nin'Oluwa, e yo" (C&S Hymn #081, Yoruba). 1. Ẹ YỌ nin'Oluwa, ẹ yọ Ẹyin ọlọkan diduro, At'ẹyin t'a se l'ayanfẹ, Mu…
1. Ẹ YỌ nin'Oluwa, ẹ yọ Ẹyin ọlọkan diduro, At'ẹyin t'a se l'ayanfẹ, Mu 'banujẹ kuro l'ọkan yin. Ẹ yọ, ẹ yọ, ẹ yọ nin' ) Oluwa, ẹ yọ. )2ce 2. Ẹ yọ n'tori Oun l'Oluwa, L'ayé ati l'ọrun pẹlu; O n j'Ọba nipa asẹ Rẹ, O l'agbara lati gbala. 3. Nigba ti ogun ba gbona, T'ọta ba fẹrẹ sẹgun yin; Ogun Jesu ti a ko ri, Pọ ju gbogbo ọta yin lọ. 4. B'ọsan d'oru mọ yin loju, T'okunkun rẹ n dẹru ba yin; Ẹ ma jẹ k'ọkan yin bajẹ, Gbẹkẹle tit'ewu yoo tan. 5. Ẹ yọ nin' Oluwa ẹ yọ, Ẹ f'orin didun yin logo; Fi duru, fere, at'ohun, Kọrin Halleluyah kikan. AMIN
Hymn 081 – E YO nin'Oluwa, e yo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia