Hymn 861 – OMO Egbe Serafu dide | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OMO Egbe Serafu dide" (C&S Hymn #861, Yoruba). ỌMỌ ẸGBẸ Séráfù dide, F'ifẹ at'aniyan dide, Jẹ ki imọlẹ rẹ tan roro,…
ỌMỌ ẸGBẸ Séráfù dide, F'ifẹ at'aniyan dide, Jẹ ki imọlẹ rẹ tan roro, Dide lati gbe Jesu ga. Ma yan nin'ọla Ọlọrun wa, Ma yan nin'ọla Ọlọrun wa, Ma yan, ma yan, Ma rin, ma yan n'nu 'fẹ Jesu. Ọmọ Ẹgbẹ Séráfù dide, F'ayọ ru agbelebu rẹ, Ma banujẹ, ma b'ohun bọ, Jesu yoo s'ẹkun rẹ d'ayọ. Ma yan nin'ọla Ọlọrun wa, Ma yan nin'ọla Ọlọrun wa, Ma yan, ma yan, Ma rin, ma yan n'nu 'fẹ Jesu. Ọmọ Ẹgbẹ Séráfù dide, Ireti rẹ ko ni saki, Baba ko ni ko ohun rẹ, Mase jẹ ko rẹ 'gbagbọ rẹ, Ma yan nin'ọla Ọlọrun wa, Ma yan nin'ọla Ọlọrun wa, Ma yan, ma yan, Ma rin, ma yan n'nu 'fẹ Jesu. Ọmọ Ẹgbẹ Séráfù dide, Oke nla yoo di pẹtẹlẹ, Bi Ọlọrun ba n se tiwa, Tani le doju 'ja kọ wa. Ma yan nin'ọla Ọlọrun wa, Ma yan nin'ọla Ọlọrun wa, Ma yan, ma yan, Ma rin, ma yan n'nu 'fẹ Jesu. Ọmọ Ẹgbẹ Séráfù dide, Jesu Oluwa fẹrẹ de, Ade 'rawọ yoo jẹ tiwa, Larin Ijọ Mimọ t'ọrun. Ma yan nin'ọla Ọlọrun wa, Ma yan nin'ọla Ọlọrun wa, Ma yan, ma yan, Ma rin, ma yan n'nu 'fẹ Jesu. AMIN Ma yan nin'ọla Ọlọrun wa, Ma yan nin'ọla Ọlọrun wa, Ma yan, ma yan, Ma rin, ma yan n'nu 'fẹ Jesu.
Hymn 861 – OMO Egbe Serafu dide | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia