Hymn 862 – OLUS'AGUNTAN, toju wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUS'AGUNTAN, toju wa" (C&S Hymn #862, Yoruba). OLUS'AGUNTAN, tọju wa, Ni ọjọ ibi yi, Fun gbogbo ọmọ-ẹhin Rẹ, N'ipa…

Hymn 862 – OLUS'AGUNTAN, toju wa | C&S Yoruba Hymnary
OLUS'AGUNTAN, tọju wa, Ni ọjọ ibi yi, Fun gbogbo ọmọ-ẹhin Rẹ, N'ipa lati sọna. B'igba idanwo wa ba pe, T'ipọnju pọ fun wa, Jẹ k'ẹmi wa sinmi le Ọ, L'adura aisinmi. F'ore-ọfẹ emi ẹbẹ, Fun wa nipa 'gbagbọ; K'a du titi a o r'oju Rẹ, T'a o si mọ okọ Rẹ. Titi O fun wa l'ara Rẹ, Ati ifẹ pipe, K'eyi jẹ igbe gbogbo wa, N ki o jẹ ki O lọ. O ki o lọ, bi ko se pe, O s'okọ Rẹ fun mi, K'O f'igbala Rẹ bukun mi, Si jẹ ki n dabi Rẹ. Jẹ ki n r'oju Rẹ kedere, 'Gba m'ba d'ori-oke, Nibi t'a r'ohun t'a gbagbọ, T'adura di iyin. AMIN

Hymn 862 – OLUS'AGUNTAN, toju wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia