Hymn 860 – OHUN t'owo re ba ni sise | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OHUN t'owo re ba ni sise" (C&S Hymn #860, Yoruba). OHUN t'ọwọ rẹ ba ni sise, Fi tọkantọkan se; Ko si ete tab'ero…

Hymn 860 – OHUN t'owo re ba ni sise | C&S Yoruba Hymnary
OHUN t'ọwọ rẹ ba ni sise, Fi tọkantọkan se; Ko si ete tab'ero n'iku, Siro 'sẹ rẹ f'ere. Jọwọ mura giri, Damure rẹ k'o le, Olukore mbọ tete, Lati kore s'aba. Sisẹ l'owurọ ayé rẹ, Nigba t'o wa l'ewe; Sisẹ nigba t'o yẹ fun 'sẹ, Ka le re le l'ayọ. Jọwọ mura giri, Damure rẹ k'o le, Olukore mbọ tete, Lati kore s'aba. Ronu ibẹrẹ ayé rẹ; S'atunse rẹ l'o yẹ; Ronu ọpọ ẹlẹgbẹ rẹ, T'o ku lai s'atunse. Jọwọ mura giri, Damure rẹ k'o le, Olukore mbọ tete, Lati kore s'aba. Awọn alore ma n ke to, P'ayé n darugbo lọ; Woli Joel ran wa l'eti, Pe ko tun s'ayọ mọ: Jọwọ mura giri, Damure rẹ k'o le, Olukore mbọ tete, Lati kore s'aba. Baba, fun wa l'eti gbigbọ, K'a yipada n'iwa; Nigba t'a fi oju de n'iku, Fun wa laye loke. Jọwọ mura giri, Damure rẹ k'o le, Olukore mbọ tete, Lati kore s'aba. AMIN Jọwọ mura giri, Damure rẹ k'o le, Olukore mbọ tete, Lati kore s'aba.

Hymn 860 – OHUN t'owo re ba ni sise | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia