Hymn 859 – KERUBU SERAFU segun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "KERUBU SERAFU segun" (C&S Hymn #859, Yoruba). KÉRÚBÙ Séráfù sẹgun, Ọpẹ ni fun Oluwa Jesu, Ẹ wo Ebenezer wa, K'ẹ ba wa…

Hymn 859 – KERUBU SERAFU segun | C&S Yoruba Hymnary
KÉRÚBÙ Séráfù sẹgun, Ọpẹ ni fun Oluwa Jesu, Ẹ wo Ebenezer wa, K'ẹ ba wa yin Oluwa l'ogo. Awa n góke lọ si Jerusalem, Laifoya awọn abinuku Jesu, Ti wọn n fẹ f'irira at'arankan, P'asẹ Oluwa wa Jesu mọlẹ )2 Ọlọrun gbe ọ leke, Ọpẹ ni fun Baba wa loke, K'o s'ogun, ko s'ọtẹ mọ, K'ẹ ba wa yin Ọlọrun l'ogo. Awa n góke lọ si Jerusalem, Laifoya awọn abinuku Jesu, Ti wọn n fẹ f'irira at'arankan, P'asẹ Oluwa wa Jesu mọlẹ )2 Sa ma rin, ki o si ma yan, Ma bẹru mọ, ko s'ewu l'ode, Ọlọrun wa pẹlu rẹ, Kini eniyan lasan le se? Awa n góke lọ si Jerusalem, Laifoya awọn abinuku Jesu, Ti wọn n fẹ f'irira at'arankan, P'asẹ Oluwa wa Jesu mọlẹ )2 Ẹ f'ogo fun Baba wa, Ẹ tun f'ogo fun Ọmọ pẹlu, Ogo fun Ẹmi Mimọ , Ọpẹ ni f'Ọlọrun Mẹtalọkan. Awa n góke lọ si Jerusalem, Laifoya awọn abinuku Jesu, Ti wọn n fẹ f'irira at'arankan, P'asẹ Oluwa wa Jesu mọlẹ )2 AMIN Awa n góke lọ si Jerusalem, Laifoya awọn abinuku Jesu, Ti wọn n fẹ f'irira at'arankan, P'asẹ Oluwa wa Jesu mọlẹ )2

Hymn 859 – KERUBU SERAFU segun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia