Hymn 851 – A DUPE lowo Oluwa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "A DUPE lowo Oluwa" (C&S Hymn #851, Yoruba). A DUPẸ lọwọ Oluwa, To da wa si d'oni, Ti ko f'ọkan adaba Rẹ le ẹranko…

Hymn 851 – A DUPE lowo Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
A DUPẸ lọwọ Oluwa, To da wa si d'oni, Ti ko f'ọkan adaba Rẹ le ẹranko lọwọ, Iku ati Esu gbogun, sibẹ ko ta wa nu, Ogo f'Ọba Mimọ julọ, Kabiyesi Ọba. Melomelo lore Rẹ, Ọba awọn Ọba, Ti pamọ ati isọ Rẹ, tabi Isẹgun ọta, Loju ala, loju ayé, tabi ti pese Rẹ, Iwosan lọna iyanu, A dupẹ Oluwa. Owo wa ko to dupẹ, Asọ ko to dupẹ, Ko s'ohun ta le fi dupẹ, bikose ohun wa, Ka f'ọkan wa fun Kristi, lati ayé yi lọ, Kayọ ọrun le jẹ tiwa, ti Kristi ti seleri. Bani owo lainiye, B'a ni 'le lainiye, Basọ wa pọ bi ti ‗Lilly‘, b'ọmọ pọ lọ titi, Ba ro pe ayọ wa tikun, rara ko iti kun, Oku ba ko ti seleri ẹru ni n'ẹru wa. Ki lo tun ba ọ lẹru, ti Jesu ko le se, Damu lo wa niwaju rẹ, pe Jesu fun ran 'wọ, Peteru pe fun ranlọwọ, ko jẹ ko ri somi, Hezekiah Ọba tun pe, O sẹgun keferi. 'Wọn to fẹjẹ ti Kristi, yoo pinu lọkan wọn, Lati yago fun Lusifa, A t'ọmọ ogun rẹ, Ija, Ibinu, Arankan ati iwa Eri, Ainifẹ ati ailanu, kọ wọn silẹ loni. A dupẹ lọwọ Oluwa Ọba awọn Ọba, Atobiju, Ẹni 'yanu, Olùgbàlà Ẹda, Ẹlẹda, Ọlọjọ oni, A juba Okọ Rẹ, Oore Rẹ pọ ju kika lọ, A dupẹ Oluwa. AMIN

Hymn 851 – A DUPE lowo Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia