Hymn 852 – E fi ope fun Oluwa, nitori o | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E fi ope fun Oluwa, nitori o" (C&S Hymn #852, Yoruba). Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori o Seun, nitori ti anu rẹ duro…
Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori o Seun, nitori ti anu rẹ duro lailai. Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun awọn, Ọlọrun Nitori ti anu rẹ duro lailai. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn Oluwa, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Fun oun nikan ti n se isẹ iyanu nla, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Fun ẹni ti o fi ọgbọn da ọrun, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Fun ẹni ti o tẹ ilẹ lori omi, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Fun ẹni ti o da awọn imọlẹ nla Nitori ti anu rẹ duro lailai. Orun lati jọba ọsan, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Osupa ati irawọ lati jỌba oru, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Fun ẹni ti o kọlu Egypt lara awọn akọbi wọn, Nitori ti anu rẹ duro lailai. O si mu Israeli jade kuro larin wọn Nitori ti anu rẹ duro lailai. Pẹlu ọwọ agbara ati apa nina Nitori ti anu rẹ duro lailai. Fun ẹni ti o pin okun pupa niya, Nitori ti anu rẹ duro lailai. O si mu Israeli kọja lọ larin rẹ, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Sugbọn o bi Farao ati ogun rẹ subu ninu okun pupa, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Fun ẹni ti o sin awọn eniyan rẹ, la aginju ja, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Fun ẹni ti o kọlu awọn Ọba nla, Nitori ti anu rẹ duro lailai. O si pa awọn Ọba olokiki, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Sihoni Ọba awọn ara Amori, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Ati Ogu Ọba Basani; Nitori ti anu rẹ duro lailai. O si fi ile wọn fun mi ni ini, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Ini fun Israeli, iransẹ rẹ: Nitori ti anu rẹ duro lailai. Ẹni ti o ranti wa ni iwa irẹlẹ wa, Nitori ti anu rẹ duro lailai. O si da wa ni ide lọwọ awọn ọta wa, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Ẹni ti o n fi Ounjẹ fun ẹda gbogbo, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun ọrun, Nitori ti anu rẹ duro lailai. Ogo ni fun Baba, etc. AMIN
Hymn 852 – E fi ope fun Oluwa, nitori o | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia