Hymn 850 – EGBE awon Angeli | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EGBE awon Angeli" (C&S Hymn #850, Yoruba). ẸGBẸ awọn angeli, Ẹgbẹ ogun ọrun, Ẹgbẹ awọn Apostel, Wọn Ẹni mimọ, Gbogbo…

Hymn 850 – EGBE awon Angeli | C&S Yoruba Hymnary
ẸGBẸ awọn angeli, Ẹgbẹ ogun ọrun, Ẹgbẹ awọn Apostel, Wọn Ẹni mimọ, Gbogbo wọn loke ọrun, N yin Ọ tọsan-toru, Ọlọrun Mẹtalọkan Ọga Ogo julọ. Lẹgbẹgbẹ l'awa pejọ, Niwaju Rẹ, Baba, Lati fi ọpẹ fun Ọ, Pẹl' awọn ọrẹ wa, Ọpẹ 'kore l'a mu wa, F'Oluwa ikore; Ọlọrun, jọ sọkalẹ, F'ogo Rẹ kun 'le yi. Larin ainiye ibi, T'o rọgba yi wa ka, Larin ayida ayé, Lẹhin 'kore esi, Awa wa f'ọpẹ fun Ọ, N'tori 'Wọ da wa si; Loni, ọdun ikore, A f'ogo f'Okọ Rẹ. 'Gba Noa rubọ ọpẹ, 'Wọ f'osumare han, Ami pe kikun omi, Ki o ba ayé mọ, Baba f'osumare han, Nitori Jesu wa, K'ipọnju oun banujẹ, Mase tun de ba wa. Obinrin opo 'gbani, Ko ri pupọ mu wa, Sugbọn o ri 'bukun gba, Fun iwọn ti o le se, Jesu, jọ yin wa loni, Jẹ k'a ri 'bukun gba, Tẹwọ gb'ọrẹ ọpẹ wa, B'o tilẹ salayé. Awa mbẹ Ọ, Ọlọrun, Gba ọkan wa pẹlu, Ọkan ẹsẹ la mu wa, Ẹgbin pọ ninu rẹ; F'Ẹjẹ Rẹ mimọ Jesu, Wẹ abawọn rẹ nu, K'ọkan ati ọrẹ wa, J'ẹbọ ọpẹ fun Ọ. AMIN

Hymn 850 – EGBE awon Angeli | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia