Hymn 847 – AWON mimo, lala pari | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "AWON mimo, lala pari" (C&S Hymn #847, Yoruba). AWỌN mimọ, lala pari, Wọn ti ja, wọn si ti sẹgun, Wọn ko fẹ ohun ija…

Hymn 847 – AWON mimo, lala pari | C&S Yoruba Hymnary
AWỌN mimọ, lala pari, Wọn ti ja, wọn si ti sẹgun, Wọn ko fẹ ohun ija mọ, Wọn da wọn 'lẹ l'ẹsẹ Jesu A! ẹyin ẹni ibukun, Isinmi yin ti daju to! Awọn mimọ, irin pari, Wọn ko tun sure ije mọ, Arẹ at' isubu d'opin, Ọta oun ẹru ko si mọ; A! ẹyin ẹni ibukun, Isinmi yin ha ti dun to! Awọn mimọ, ajo pari, Wọn ti gun s'ilẹ ibukun, Iji ko dẹruba wọn mọ, Igbi omi ko n'ipa mọ; A! ẹyin ẹni ibukun, Ẹ n sinmi n'ib'alafia. Awọn mimọ, oku wọn sun, Ninu ile, awọn n sọna, Titi wọn yoo fi jinde, Lati fi ayọ goke lọ; A! ẹni 'bukun, ẹ koriin; Oluwa at'Ọba yin mbọ. Ọlọrun wọn, 'Wọ l'a n ke pe, Jesu, bẹbẹ fun wa l'oke; Ẹmi Mimọ, Olutọ wa, F'ore-ọfẹ fun wa d'opin; K'a le b'awọn mimọ sinmi, Ni Paradise pẹlu Rẹ. AMIN

Hymn 847 – AWON mimo, lala pari | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia