Hymn 848 – ERO s'orun l'awa n se | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ERO s'orun l'awa n se" (C&S Hymn #848, Yoruba). ERO s'ọrun l'awa n se, Ayé l'ọja ọrun n'ile wa; Atipo ni awa jẹ o ,…

Hymn 848 – ERO s'orun l'awa n se | C&S Yoruba Hymnary
ERO s'ọrun l'awa n se, Ayé l'ọja ọrun n'ile wa; Atipo ni awa jẹ o , Ayé l'ajo, ọrun n'ile wa; Gbogbo ewu lo duro o, Yika wa l'ọjọ gbogbo, Ẹkun l'oni, ẹrin l'ọla; Ayé l'ọja, ọrun n'ile wa. Iransẹ ti sun n'nu Oluwa, Ayé l'ọja, ọrun n'ile wa; Isẹ d'opin, ija d'opin, Ayé l'ọja, ọrun n'ile wa; O ti jagun f'Oluwa, O bọ s'ayọ Baba rẹ; Titi la o se 'ranti rẹ, Ayé l'ọja ọrun n'ile wa. Ọmọde n ku, agba n ku o, Ayé l'ọja, ọrun n'ile wa; K'a ku n'nu Jesu lo dara, Ayé l'ọja, ọrun n'ile wa; Ka lọ 'gba wa fun Jesu, 'Tori ọjọ iku mbẹ; Ko s'ẹni ti ko ni ku o, Ayé l'ọja, ọrun n'ile wa. Lọd' Oluwa ni 'sinmi mbẹ, Ayé l'ọja, ọrun n'ile wa; 'Banujẹ kan ko si nibẹ, Ayé l'ọja, ọrun n'ile wa; Ọpọ ibugbe lo wa, T'Ọlọrun ti ko s'ọrun, F'awọn to ba sin dopin, Ayé l'ọja, ọrun n'ile wa. Iransẹ naa yọ n'nu Oluwa, Ayé l'ọja, ọrun n'ile wa; O ti ri Jesu to fẹ ọ, Ayé l'ọja, ọrun n'ile wa; Baba rere tọju wa, K'ayé mase gbe wa lọ! K'a le j'ẹni idalare; Ayé l'ọja, ọrun n'ile wa. AMIN

Hymn 848 – ERO s'orun l'awa n se | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia