Hymn 845 – OLORUN to fe Abraham | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN to fe Abraham" (C&S Hymn #845, Yoruba). ỌLỌRUN to fẹ Abraham, T'o ti se ore re; Pe ni 'ru ọmọ rẹ layé, Yoo dabi…

Hymn 845 – OLORUN to fe Abraham | C&S Yoruba Hymnary
ỌLỌRUN to fẹ Abraham, T'o ti se ore re; Pe ni 'ru ọmọ rẹ layé, Yoo dabi irawọ; O fi Isaaki seleri, Lati gba ilẹ na; O mu ileri na sẹ fun, Jakọbu ọmọ rẹ. K'a damure lati jagun (2) K'a damure e (2) K'a damure lati jagun. Iwọ to gbọ ti Mose, Lori oke Sinai; Iwọ to pe Samueli, Nigba t'o wa lewe; Iwọ to pẹlu Dafidi, T'o sẹgun Golayat, Ẹ wa di Ijọ Séráfù, Lamure ododo. K'a damure lati jagun (2) K'a damure e (2) K'a damure lati jagun. Gbọ bi Jesu Oluwa wa, Ti se ileri fun; Awọn Aposteli 'gbani, Lati j'alagbara; Nigba wọn gba Ẹmi Mimọ , Wọn fi ayọ sisẹ; Irapada d'orin fun wọn. Titi d'oke ọrun. K'a damure lati jagun (2) K'a damure e (2) K'a damure lati jagun. Kérúbù ati Séráfù, Ẹ damure giri; Ki Ẹgbẹ Aladura, Mura lati sisẹ, Ileri ti Oluwa se, Nipa ti otitọ, K'a ranti a o segun, Ni ọjọ ikẹhin. K'a damure lati jagun (2) K'a damure e (2) K'a damure lati jagun. Ẹyin ẹni irapada, Ẹ kọrin Igbala; Si ẹni ti o fẹ wa, To f'ẹjẹ Rẹ ra wa, Lati oko ẹru wa, Lọ si ilẹ Kenaani, Ilu Jerusalemu, Lọdọ Jesu Ọba. K'a damure lati jagun (2) K'a damure e (2) K'a damure lati jagun. Ẹni to ran Mose lọwọ, Baba Aladura, Lati se isẹ Alakoso, Séráfù, Kérúbù, Fi 'sẹgun fun de isẹgun, Lati ja ajaye, La ti gba ade Ogo na, B'awọn Woli saju. K'a damure lati jagun (2) K'a damure e (2) K'a damure lati jagun. AMIN K'a damure lati jagun (2) K'a damure e (2) K'a damure lati jagun.

Hymn 845 – OLORUN to fe Abraham | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia