Hymn 844 – ONA kan l'o n toka s'orun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ONA kan l'o n toka s'orun" (C&S Hymn #844, Yoruba). ỌNA kan l'o n tọka s'ọrun, Isina ni 'yoku, Hiha si l'oju ọna na,…
ỌNA kan l'o n tọka s'ọrun, Isina ni 'yoku, Hiha si l'oju ọna na, Awọn Kristian l'o fẹ. Lat' ayé, o lo tarata, O si la ewu lọ; Awọn ti n f'igboya rin in, Y'o d'ọrun nikẹhin. Awọn ewe y'o ha ti se, Le la ewu yi ja? 'Tori idẹkun pọ l'ọna, F'awọn ọdọmọde! Gbigboro l'ọna t'ọpọ n rin, O si tẹju pẹlu! Mo si mo pe lati dẹsẹ, Ni wọn se n rin nibẹ. Sugbọn k'ẹsẹ mi ma ba ye, Ki n ma si sako lọ, Oluwa, jọ s'Olutọ mi, Emi ki o sina. Njẹ mo le lọ l'ai s'ifoya, Ki n gbẹkẹl' ọrọ Rẹ; Apa Rẹ y'o s'aguntan Rẹ, Y'o si ko wọn de'le. Bẹni n ó la ewu yi ja, Nipa itọju Rẹ? N ó tẹjumọ 'bode ọrun, Titi n ó fi wọle. AMIN
Hymn 844 – ONA kan l'o n toka s'orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia