Hymn 834 – A N SORO ile 'bukun ni | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "A N SORO ile 'bukun ni" (C&S Hymn #834, Yoruba). A N SỌRỌ ilẹ 'bukun ni, Ilẹ didan at'ilẹ ẹwa; 'Gba gbogbo l'a n so…

Hymn 834 – A N SORO ile 'bukun ni | C&S Yoruba Hymnary
A N SỌRỌ ilẹ 'bukun ni, Ilẹ didan at'ilẹ ẹwa; 'Gba gbogbo l'a n so t'ogo rẹ; Y'o ti dun to lati de 'bẹ. A n sọrọ ita wura rẹ, Ọsọ odi rẹ ti ko l'ẹgbẹ; Faji rẹ ko se fẹnu sọ; Y'o ti dun to lati de 'bẹ. A n sọ p'ẹsẹ ko si nibẹ, Ko s'aniyan at'ibanujẹ, Pẹlu 'danwo lode, ninu; Y'o ti dun to lati de 'bẹ. A n sọrọ orin iyin rẹ, Ti a ko le f'orin ayé we; B'o ti wu k'orin wa dun to, Y'o ti dun to lati de 'bẹ. A n sọrọ isin ifẹ rẹ, Ti agbada t'awọn mimọ n wọ, Ijọ akọbi ti oke, Y'o ti dun to lati de 'bẹ. Jọ, Oluwa, t'ibi t'ire, Sa se ẹmi wa yẹ fun ọrun; Laipẹ, awa na yoo mọ, B'o ti dun to lati de 'bẹ . AMIN

Hymn 834 – A N SORO ile 'bukun ni | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia