Hymn 833 – AJA ni gbo Ekun a ja | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AJA ni gbo Ekun a ja" (C&S Hymn #833, Yoruba). AJA ni gbo Ẹkun a ja, Bẹ l'a sa s'ẹda wọn; Ogidan, l'ola iju, L'akọmọ…
AJA ni gbo Ẹkun a ja, Bẹ l'a sa s'ẹda wọn; Ogidan, l'ola iju, L'akọmọ l'ai l'abẹ. Sugbọn eniyan l'a da yin, Ẹ hu wa bi ọmọ; K'ẹ mase ba ara yin ja, Ere ni k'ẹ ma se. Bi ọmọ-rere Maria, Ni k'iwa yin tutu; K'ẹ pọ n'ifẹ bi Oluwa, Jesu Ọm'-Ọlọrun. Ẹni jẹjẹ bi aguntan, Ti iwa Rẹ wu ni, Eniyan ati Ọlọrun, N'idagba Rẹ si wu. Oluwa gunwa bi Ọba, L'ori 'tẹ Rẹ lọrun; O n wo aw'ọmọ t'o n'ifẹ, O si n sami si wọn. AMIN
Hymn 833 – AJA ni gbo Ekun a ja | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia