Hymn 832 – A DUPE lowo Jehofa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "A DUPE lowo Jehofa" (C&S Hymn #832, Yoruba). A DUPẸ lọwọ Jehofa, Ọba Onibu-ọrẹ; Fun isẹgun t'o se fun wa, Larin ọdun…
A DUPẸ lọwọ Jehofa, Ọba Onibu-ọrẹ; Fun isẹgun t'o se fun wa, Larin ọdun t'o kọja. Awa si n jo, awa si n yọ, Fun idasi wa oni; Ayọ kun ọkan wa loni, Ogo fun Mẹtalọkan. Ọjọ ayọ l'oni fun wa, Awa si n sẹ'sin ọrọ; Kérúbù ati Séráfù, Ẹ jẹ k'a jo yin Baba Awa si n jo, awa si n yọ, Fun idasi wa oni; Ayọ kun ọkan wa loni, Ogo fun Mẹtalọkan. Jesu Olori Ẹgbẹ wa, Jẹ k'a ri Ọ l'arin wa; Awa f'iyin fun Ọ loni, Fun idasi ẹmi wa. Awa si n jo, awa si n yọ, Fun idasi wa oni; Ayọ kun ọkan wa loni, Ogo fun Mẹtalọkan. Kérúbù ati Séráfù, Awa j'ayanfẹ ọmọ; Fun Ọlọrun Mẹtalọkan, Ọba Awimayẹhun. Awa si n jo, awa si n yọ, Fun idasi wa oni; Ayọ kun ọkan wa loni, Ogo fun Mẹtalọkan. Gbogbo ajẹ t'o wa layé, Agbara wọn ti wọ 'mi; Ni agbara Mẹtalọkan, Awa y'o sẹgun esu Awa si n jo, awa si n yọ, Fun idasi wa oni; Ayọ kun ọkan wa loni, Ogo fun Mẹtalọkan. Ọjọ ayé wa n lo s'opin, Ẹ jẹ k'a mura s'ise, Gbogbo isẹ t'awa yoo se, Ọkan ki yoo lo lasan Awa si n jo, awa si n yọ, Fun idasi wa oni; Ayọ kun ọkan wa loni, Ogo fun Mẹtalọkan. A ki Baba Aladura, K'Ọlọrun ko bukun ọ; Ade Ogo y'o jẹ tirẹ, L'Agbara Mẹtalọkan. Awa si n jo, awa si n yọ, Fun idasi wa oni; Ayọ kun ọkan wa loni, Ogo fun Mẹtalọkan. AMIN Awa si n jo, awa si n yọ, Fun idasi wa oni; Ayọ kun ọkan wa loni, Ogo fun Mẹtalọkan.
Hymn 832 – A DUPE lowo Jehofa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia