Hymn 835 – GBOGBO Egbe Serafu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "GBOGBO Egbe Serafu" (C&S Hymn #835, Yoruba). GBOGBO Ẹgbẹ Séráfù, Foriti, ẹ foriti; Ma jẹ k'o rẹ gbogbo yin, Ẹ foriti,…
GBOGBO Ẹgbẹ Séráfù, Foriti, ẹ foriti; Ma jẹ k'o rẹ gbogbo yin, Ẹ foriti, Ninu irin-ajo rẹ, Ẹfufu lile le ja, Ja fun 'sẹ rẹ ma bẹru, Sa foriti. Kérúbù pẹlu Seraf' Foriti, ẹ foriti; Awọn Woli isaju, Wọn foriti; Mura si 'sẹ, ma w'ẹhin, Baba y'o gb'adura rẹ; Ẹ foriti ipọnju, Sa foriti. Ẹgun le wa lọna, Foriti, ẹ foriti, W'oke sile 'bukun ni, Ẹ foriti; Ranti ọrọ to n wi pé, Ẹ o fi iyẹ goke‖, Lagbara Mẹtalọkan, A o gb'ade. AMIN
Hymn 835 – GBOGBO Egbe Serafu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia