Hymn 827 – MOSE Orimolade | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "MOSE Orimolade" (C&S Hymn #827, Yoruba). MOSE Orimọlade, Ni Olukọ wa; Ọlọrun ran s'ayé; Lati d'ẹgbẹ yi silẹ, Kérúbù,…
MOSE Orimọlade, Ni Olukọ wa; Ọlọrun ran s'ayé; Lati d'ẹgbẹ yi silẹ, Kérúbù, Séráfù l'o sọ)2 Orukọ Ẹgbẹ na. ) Ọlọrun Tunọlase, Ran Ẹmi rẹ si wa, Ka mase se aseti, Ninu adura wa. Gbohun-gbohun jọ ) gbọ tiwa, ) 2 B'o ti gbọ t'Elijah. ) Ma jẹ k'esu tan wa, Lati se Tunọlase, Ka ma d'ẹni egbe, Ni ọjọ ikẹhin. Mẹtalọkan jọ gbọ tiwa )2 Fun wa n'ida Ẹmi. ) Ajakalẹ arun to mbọ, Kristi dabobo wa; Ki ọmọ Tunọlase, Ma nipin ninu rẹ. Awimayẹhun, gbọ tiwa,) B'o ti gbọ ti Joshua. )2 Ranti Majẹmu ni, Baba afin Ọrun; Pe ọmọ Tunọlase, Ki yoo rahun layé, Olupese, jọ gbọ tiwa ) Ka ma tosi layé )2 Lọnakọna t'ọta, Ba n gbogun rẹ si wa; Baba Olusẹgun, Sẹgun lọgan fun wa. Oluwa Ọlọrun Ọm‘ogun) Ma jẹ k'oju ti wa )2 Israeli laginju, K'ọna Mose silẹ; Wọn kun si laginju, Wọn fẹrẹ segbe tan. Edumare, jọwọ gba wa ) Ka ma segbe bi wọn. )2 Gbogbo ẹyin tẹ duro, Lati jẹ Ọmọ Mose; Olupilẹsẹ IYE, Yoo di yin mu dopin. Ọm' Alade Alafia )2 F'alafia fun wa. ) Ẹyin tẹ n sọkun ọkan, Fun gbogbo aini yin; Ẹlẹda, Olupese, Ko ni gbagbe yin lai. Nitori Jesu Oluwa )2 Tete da wa lohun ) A n lọ si ile wa, F'ogun ọrun yi wa ka, Ki gbogbo ibi ayé, Ma le se wa nibi. P'Ajẹ, Oso, Sanpọnnọ ) run, )2 F'awa ọmọ Jesu. ) Nigba t'opin ba si de, Lati ihin lọrun; MOSE ORIMỌLADE Silẹkun Ọrun fun wa, Ka si gbohun Jesu ) Oluwa, )2 Bọ s'ayọ Baba rẹ. ) Baba Aladura, Ti Baba gbe dide, K'Ọlọrun ran lọwọ, Ko gbọwọ rẹ soke, Edumare, jọ gbọ tirẹ )2 B'o ti gbọ ti Mose. ) AMIN
Hymn 827 – MOSE Orimolade | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia