Hymn 828 – ONIGBAGBO, e wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ONIGBAGBO, e wa" (C&S Hymn #828, Yoruba). ONIGBAGBỌ, ẹ wa, Israeli t'emi, Jesu mbẹbẹ pupọ pupọ, Bi Alagbawi wa. Ẹ ho,…

Hymn 828 – ONIGBAGBO, e wa | C&S Yoruba Hymnary
ONIGBAGBỌ, ẹ wa, Israeli t'emi, Jesu mbẹbẹ pupọ pupọ, Bi Alagbawi wa. Ẹ ho, ẹ yo, f'inu didun gberin, Ẹyin 'Male ati Keferi, Ẹ wa si'mọlẹ na. Nigba t'ọjọ 'dajọ ba de, Bawo ni 'wọ o ti wi? Gba t'o pin fun 'kaluku, Gẹgẹ bi isẹ rẹ. Ẹ ho, ẹ yo, f'inu didun gberin, Ẹyin 'Male ati Keferi, Ẹ wa si'mọlẹ na. Nigba ti n wasu nijọsi, Iwọ ko si nibẹ? Mase tun wi awawi mọ, Bọ sinu imọlẹ Ẹ ho, ẹ yo, f'inu didun gberin, Ẹyin 'Male ati Keferi, Ẹ wa si'mọlẹ na. Wo 'sẹ 'yanu Olodumare, B'o ti yọ lara wa, Ko s'ọrọ t'a tun le gbọ mọ, Bi ko s'ọrọ Ọlọrun. Ẹ ho, ẹ yo, f'inu didun gberin, Ẹyin 'Male ati Keferi, Ẹ wa si'mọlẹ na. Ẹ mura si adura, Kerub' ma jafara, Ẹ gbe ida 'sẹgun soke, Awa yoo si sẹgun. Ẹ ho, ẹ yo, f'inu didun gberin, Ẹyin 'Male ati Keferi, Ẹ wa si'mọlẹ na. Jesu Olori Ẹgbẹ wa, Fun wa ni isẹgun, A dupẹ lọwọ Rẹ Baba, P'awa n ri 'bere gba. Ẹ ho, ẹ yo, f'inu didun gberin, Ẹyin 'Male ati Keferi, Ẹ wa si'mọlẹ na. Asiwaju ninu Ẹgbẹ, Ẹ gbadura si MI, JEHOFA ALLIYUMION Ni Orukọ mi jẹ. Ẹ ho, ẹ yo, f'inu didun gberin, Ẹyin 'Male ati Keferi, Ẹ wa si'mọlẹ na. Ẹni duro ti o n woran, At' ẹni t'o joko, Ẹ gbọ ipe Oluwa wa, B'o ti n dun pe ma bọ. Ẹ ho, ẹ yo, f'inu didun gberin, Ẹyin 'Male ati Keferi, Ẹ wa si'mọlẹ na. Nigba t'a ba pari 'sẹ wa, Ti a ba si d'ọrun, Awa yoo pẹl' awọn t'ọrun, Lati ma juba Rẹ. Ẹ ho, ẹ yo, f'inu didun gberin, Ẹyin 'Male ati Keferi, Ẹ wa si'mọlẹ na. A mọ p'ere wa ko si l'ayé, Sugbọn o wa l'ọrun, Ẹyin Ẹgbẹ ẹ d'amure, K'a ba le lọ gb'ade. Ẹ ho, ẹ yo, f'inu didun gberin, Ẹyin 'Male ati Keferi, Ẹ wa si'mọlẹ na. Ẹ f'Ogo fun Baba loke, Ẹ f'Ogo fun Ọmọ, Ẹ f'Ogo fun ẸMI MIMỌ , Mẹtalọkan lailai. Ẹ ho, ẹ yọ, f'inu didun gberin, Ẹyin 'Male ati Keferi, Ẹ wa si 'mọlẹ na. AMIN Ẹ ho, ẹ yọ, f'inu didun gberin, Ẹyin 'Male ati Keferi, Ẹ wa si 'mọlẹ na.

Hymn 828 – ONIGBAGBO, e wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia