Hymn 825 – NIGBA ti'gbi aye yi ba mbu lu o | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "NIGBA ti'gbi aye yi ba mbu lu o" (C&S Hymn #825, Yoruba). NIGBA ti'gbi ayé yi ba mbu lu ọ, T'ọkan rẹ n poruru t'o ro…

Hymn 825 – NIGBA ti'gbi aye yi ba mbu lu o | C&S Yoruba Hymnary
NIGBA ti'gbi ayé yi ba mbu lu ọ, T'ọkan rẹ n poruru t'o ro pe o gbe; Siro ibukun rẹ, ka wọn l'ọkọkan, Ẹnu yoo si ya o f'ohun t'Oluwa se. Siro ibukun rẹ, ka wọn l'ọkọkan, Siro ibukun rẹ, w'ohun t'Oluwa se, Siro ibukun rẹ, ka wọn l'ọkọkan; Ẹnu yoo si ya o f'ohun t'Oluwa se. Aniyan ha se si kun ọkan rẹ bi? Agbelebu rẹ ha wuwo rinrin bi? Siro ibukun rẹ, le 'yemeji lọ, Ọkan rẹ yoo si kun f'orin iyin. Siro ibukun rẹ, ka wọn l'ọkọkan, Siro ibukun rẹ, w'ohun t'Oluwa se, Siro ibukun rẹ, ka wọn l'ọkọkan; Ẹnu yoo si ya o f'ohun t'Oluwa se. B'o ti n wo ẹlomi to se gbẹdẹ fun, Ronu wi pé Jesu ko ni gbagbe rẹ; Siro ibukun rẹ t'o ko fowo ra, Ere ti o duro de ọ l'oke ọrun, Siro ibukun rẹ, ka wọn l'ọkọkan, Siro ibukun rẹ, w'ohun t'Oluwa se, Siro ibukun rẹ, ka wọn l'ọkọkan; Ẹnu yoo si ya o f'ohun t'Oluwa se. Njẹ ninu idamu rẹ l‘ayé yi, Ma so 'reti nu, oluwa wa, fun ọ; Siro ibukun rẹ, f'awọn Angeli rẹ, Yoo duro ti o titi de opin. Siro ibukun rẹ, ka wọn l'ọkọkan, Siro ibukun rẹ, w'ohun t'Oluwa se, Siro ibukun rẹ, ka wọn l'ọkọkan; Ẹnu yoo si ya ọ f'ohun t'Oluwa se. AMIN Siro ibukun rẹ, ka wọn l'ọkọkan, Siro ibukun rẹ, w'ohun t'Oluwa se, Siro ibukun rẹ, ka wọn l'ọkọkan; Ẹnu yoo si ya ọ f'ohun t'Oluwa se.

Hymn 825 – NIGBA ti'gbi aye yi ba mbu lu o | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia