Hymn 824 – JE K'A l'ayo ninu Jesu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JE K'A l'ayo ninu Jesu" (C&S Hymn #824, Yoruba). JẸ K'A l'ayọ ninu Jesu, Ọba Alayọ ni Jesu, Ẹnikẹni to ba r'ayọ Rẹ…
JẸ K'A l'ayọ ninu Jesu, Ọba Alayọ ni Jesu, Ẹnikẹni to ba r'ayọ Rẹ gba, 'Banujẹ rẹ y'o si fo lọ 'Wọ sa gba Orukọ Rẹ gbọ, Ki o si tun gbẹkẹle; Ko si m'adun to wa nin' ẹjẹ Rẹ, 'Banujẹ rẹ y'o si fo lọ. Kérúbù ati Séráfù, 'Wọ ha tun n banujẹ bi? Kristi n sọ fun ọ, ke Haleluya, 'Banujẹ rẹ y'o si fo lọ. Esu lo ha n dẹru ba ọ? Oso tabi ajẹ ni? Pe Orukọ Jesu nigba gbogbo, 'Banujẹ rẹ y'o si fo lọ. K'a ni 'fẹ si gbogbo ayé, Ki se s'ọmọ ẹgbẹ nikan, 'Gbana adura rẹ y'o si goke, 'Banujẹ rẹ y'o si fo lọ. Gbogbo ẹyin ẹda ayé; Juba orukọ Jesu; Orukọ yi to fun 'banujẹ rẹ, 'Banujẹ rẹ y'o si fo lọ. Ranti pe Oun l'Ẹni 'Yanu, Ọba Oludamọran; Alagbara, Baba ayérayé, Alade Alafia. A f'ogo fun Baba l'oke, A f'ogo fun Ọmọ Rẹ; Ogo ni fun Ẹmi t'o n dari wa, Mẹtalọkan wa gb'ọpẹ wa. AMIN
Hymn 824 – JE K'A l'ayo ninu Jesu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia