Hymn 823 – AGO Re wonni ti ni | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AGO Re wonni ti ni" (C&S Hymn #823, Yoruba). AGỌ Rẹ wonni ti ni ) ẹwa to, Oluwa, ) Ọkan mi n fa si'le ọrun)2ce Tor'…
AGỌ Rẹ wonni ti ni ) ẹwa to, Oluwa, ) Ọkan mi n fa si'le ọrun)2ce Tor' awọn ẹyẹ Ọrun ) wọn nile lor'igi ) Alapandẹdẹ wọn n tẹ ) itẹ o. ) Sugbọn ibukun ni F'awọn Ẹgbẹ Séráfù; Awa nile, ile ayọ, lọdọ Oluwa; Ibukun o, Haleluya, Ibukun o, Ibukun o, Haleluya, Ibukun o. Ọkan mi n fa nitotọ sile o) S'agbala Ọba Mimọ o; )2ce N ó ma lọ lat'ipa de'pa) titi o, ) N ó fi gunlẹ s'ebute Ogo) Sugbọn ibukun ni F'awọn Ẹgbẹ Séráfù; Awa nile, ile ayọ, lọdọ Oluwa; Ibukun o, Haleluya, Ibukun o, Ibukun o, Haleluya, Ibukun o. Ọjọ kan ninu agbala Oluwa, O san ju ẹgbẹrun ọjọ lọ;)2ce Ore-ọfẹ pẹlu ibukun jẹ, t'Ọlọrun, Ibukun ni f'ẹni to sin. Sugbọn ibukun ni F'awọn Ẹgbẹ Séráfù; Awa nile, ile ayọ, lọdọ Oluwa; Ibukun o, Haleluya, Ibukun o, Ibukun o, Haleluya, Ibukun o. Mimọ, Pipe l'Ọbaluwayé ) Mimọ o, ) Angeli ẹ wa ka jumọ ) sin o; ) Ẹni ba sin Ẹrintunde ) titi d'opin, ) 2ce Yoo gba ade iye ) l'ebute ogo. ) Sugbọn ibukun ni F'awọn Ẹgbẹ Séráfù; Awa nile, ile ayọ, lọdọ Oluwa; Ibukun o, Haleluya, Ibukun o, Ibukun o, Haleluya, Ibukun o. AMIN Sugbọn ibukun ni F'awọn Ẹgbẹ Séráfù; Awa nile, ile ayọ, lọdọ Oluwa; Ibukun o, Haleluya, Ibukun o, Ibukun o, Haleluya, Ibukun o.
Hymn 823 – AGO Re wonni ti ni | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia