Hymn 822 – EGBE Iye l'Egbe Seraf | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EGBE Iye l'Egbe Seraf" (C&S Hymn #822, Yoruba). ẸGBẸ Iye l'Ẹgbẹ Seraf, Ẹgbẹ Adura ni: Ẹgbẹ ti ko gbẹkẹ l'egbo, Ẹgbẹ ti…
ẸGBẸ Iye l'Ẹgbẹ Seraf, Ẹgbẹ Adura ni: Ẹgbẹ ti ko gbẹkẹ l'egbo, Ẹgbẹ ti ko gbẹkẹl' ewe, Kristi nikan ni 'Mọlẹ, Oun l'Oluwosan wọn. Ẹyin Olor' Ẹgbẹ Seraf, To wa n'ilu Eko; Ẹ sisẹ t'Oluwa ran yin, Ki se pẹl' ere 'jẹkujẹ, Kẹ ma w'ẹgan, kẹ ma wo'ya Kẹ le gbade Ogo. Ẹyin Leader Ẹgbẹ Seraf, Ẹ s'otitọ d'opin; Ati gbogb' Ẹgbẹ Aladura, Ati Baba nla Mejila, Ẹ ma wo'ya, ẹ ma w'ẹgan, Kẹ le gade Ogo. Ẹgbẹ Ọdọ-'kunrin Ijọ, Ẹ ma fa sẹhin o, Ati gbogbo Ẹgbẹ Esther, At' Ẹgbẹ F'Og' Ọlọrun han, Ẹ ma wo'ya, ẹ ma w'ẹgan, Kẹ le gbade Ogo. Ẹgbẹ Mary, Ẹgbẹ Marta, Ẹ ma fa sẹhin mọ; Ẹgbẹ Ọm' gun Igbala, Ati awọn eto gbogbo; Ẹ ma wo'ya, ẹ ma w'ẹgan, Kẹ le gbade Ogo. Mesaiah Nla Ọba Ogo, S'alatilẹhin wa; Ma jẹ k'ọmọ rẹ rahun mọ, Ka ma j'egun kẹhin ẹran, Ka ma f'akisa par' asọ, Jẹ k'ara ko tu wa. Jesu Ọba Ẹgbẹ Seraf' Ma jẹ ka padanu: L'ọjọ ta o se'dajọ ayé, T'oju ayé, ọrun yoo pe, Mesaiah Nla Ọba Ogo, Jẹ ka le d'ọdọ Rẹ. AMIN
Hymn 822 – EGBE Iye l'Egbe Seraf | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia