Hymn 821 – E JE K'A yin Olugbala | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "E JE K'A yin Olugbala" (C&S Hymn #821, Yoruba). Ẹ JẸ K'A yin Olùgbàlà, T'o da Ẹmi wa si di oni, Nitori a ko mọ ọjọ,…

Hymn 821 – E JE K'A yin Olugbala | C&S Yoruba Hymnary
Ẹ JẸ K'A yin Olùgbàlà, T'o da Ẹmi wa si di oni, Nitori a ko mọ ọjọ, T'o mbọ wa se 'dajọ ayé; Ọjọ kan mbọ 'gba ayé ba pin, Kérúbù yoo kọ'rin Aleluya. Ọjọ 'dajọ ọjọ ẹru, 'Gba Jesu yoo ya Àgùntàn Rẹ, Kuro ninu agbo esu; 'Gbana ipe nla yoo si dun, Gbogbo ayé yoo wa si idajọ, Séráfù yoo kọ'rin Aleluya. Awọn ẹlẹsẹ yoo fẹ sa, Kuro niwaju Olùgbàlà, Sugbọn iye ko ni si mọ, Wọn yoo ke gba mi Oluwa, Sugbọn ọjọ anu kọja, Kérúbù yoo ma kọ Aleluya. Ara mi jẹ k'a gba adura, S'Ọlọrun Mẹtalọkan, Tori oun lo da ayé, Ati gbogbo ẹda 'nu rẹ, Yoo si ko awọn Tirẹ jọ, Lati ma kọrin niwaju itẹ. AMIN

Hymn 821 – E JE K'A yin Olugbala | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia