Hymn 817 – EMI ti n ji oku dide | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EMI ti n ji oku dide" (C&S Hymn #817, Yoruba). ẸMI ti n ji oku dide, A wolẹ niwaju Rẹ, Na 'wọ emi 'yẹ Rẹ si wa, Ko sọ…

Hymn 817 – EMI ti n ji oku dide | C&S Yoruba Hymnary
ẸMI ti n ji oku dide, A wolẹ niwaju Rẹ, Na 'wọ emi 'yẹ Rẹ si wa, Ko sọ gbogbo wa d'ọtun; Ọmọ Baba to d'eniyan, Woli, Alufa, Oluwa, Olugbala, Olugbala, Olugbala, gba wa la. Ẹgbẹ Kérúbù ayé yi, Ẹ se ara yin lọkan; Ẹgbẹ Séráfù ayé yi, Ẹ fi ọkan kan sise; Ran wa lọwọ ka sisẹ Rẹ, Ma mase se aseti; Olugbala, Olugbala, Olugbala, gba wa la. Ma sisẹ l'orukọ Jesu, Mase wo awọn ẹlẹgan; Si Matteu ori kẹwa, W'ẹsẹ kẹrindilogun, Sọkalẹ ninu ọlanla, Sarin Ẹgbẹ Séráfù. Olugbala, Olugbala, Olugbala, gba wa la. F'ojurere wo 'dapọ wa, F'ọrọ mimọ Rẹ ye wa, Fitila t'o ran sarin wa, Ma ba wa b'ororo si; Nigba t'ọta ba sunmọ wa, Jesu, jọwọ sunmọ wa. Olugbala, Olugbala, Olugbala, gba wa la. Okunkun yoo b'oju ọrun, Isẹlẹ nla y'o si sẹ, Awọn irawọ y'o ma ja, Gẹgẹ bi ọjọ ti n ro, Ẹ ma jafara adura, Gbogbo ẹyin eniyan mi. Olugbala, Olugbala, Olugbala, gba wa la. Nigba t'o ba d'ọjọ kẹhin, T'ọmọ ko ni mọ baba, Ma doju ti wa l'ọjọ na, Gb'awa Ẹgbẹ Séráfù; Ran wa lọwọ ka sisẹ Rẹ, K'a le ma ja f'otitọ. Olugbala, Olugbala, Olugbala, gba wa la. Ẹ f'ogo fun Baba loke, Ẹ f'ogo fun Ọmọ Rẹ, Ẹ f'ogo fun Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan a juba, Oungbẹ rẹ ma n gbẹ ọkan wa Fi mana ọrun bọ wa. Olùgbàlà, Olùgbàlà, Olùgbàlà, gba wa la. AMIN Olùgbàlà, Olùgbàlà, Olùgbàlà, gba wa la.

Hymn 817 – EMI ti n ji oku dide | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia