Hymn 816 – JESU Iwo Oba mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU Iwo Oba mi" (C&S Hymn #816, Yoruba). JESU Iwọ Ọba mi, Iwọ ni mo gbẹkẹle, L'ayé yi n ko l'ẹnikan, Lẹhin Rẹ 'Wọ Ọba…
JESU Iwọ Ọba mi, Iwọ ni mo gbẹkẹle, L'ayé yi n ko l'ẹnikan, Lẹhin Rẹ 'Wọ Ọba mi, 'Tori naa gbe mi leke, Gbe mi bori ọta mi, Ki n layọ ki n ni'sẹgun, L'ọjọ ayé mi gbogbo. Fun mi ni ore-ọfẹ, Se mi yẹ l'ẹni tirẹ; S'ayé mi d'ire fun mi, 'Wọ t'o sọ ayé Esther, rere fun nigbani; Wa s'ayé mi di rere, Jẹ ki im'ọta le d'ofo. Gbe mi leke, mo fẹ bẹ, 'Wọ Ọba agbara gbogbo, Ipa ọta ko to nkan, Niwaju agbara Rẹ, 'Tori na, Ẹlẹda mi, Pa agbara ọta run, K'ọta ma yọ mi lẹnu, Gbe mi leke isoro. 'Wọ ti wa k'ayé to wa, 'Wọ ti wa k'ọrun to wa, 'Tori na Jesu temi, Jẹ k'ọla Rẹ han fun mi; Tobẹ t'emi naa yoo ri, T'ayé yoo si ri pẹlu, Pe 'Wọ l'agbara Gbogbo. Fi Ọla Rẹ yi mi ka, Fi Ogo Rẹ yi mi ka, K'agbara Rẹ s'abo mi, K'orukọ Rẹ s'abo mi, Tobẹ ti n o di tirẹ, K'ayé ma le ridi mi, K'owo esu ma te mi, Tobẹ k'ayé mi l'ayọ. Gba mo ba si de ọrun, Fun mi ni ipo lọdọ Rẹ, Ki n j'ẹni ọwọ 'tun Rẹ, Ki n yẹ ni ori itẹ Rẹ, 'Gbana l'ayọ mi y'o kun, Nin' ogo ti ko l'opin, Ninu ayọ ti ki tan, Ninu ọla ti ki sa. AMIN
Hymn 816 – JESU Iwo Oba mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia