Hymn 818 – ALAFIA ni fun Ijo mimo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ALAFIA ni fun Ijo mimo" (C&S Hymn #818, Yoruba). ALAFIA ni fun Ijọ mimọ, Ta da silẹ fun 'gbega, Krist' l'Eko. Alafia…

Hymn 818 – ALAFIA ni fun Ijo mimo | C&S Yoruba Hymnary
ALAFIA ni fun Ijọ mimọ, Ta da silẹ fun 'gbega, Krist' l'Eko. Alafia ni fun ẹnikẹni, T'o n'orukọ nin' Ijọ mimọ yi. Alafia ni fun awọn wọnni, T'o jẹri Kristi de oju iku. Alafia ni fun awọn wọnni, T'o forit' ipọnju titi dopin. Alafia ni fun awọn wọnni, T'o sisẹ Kristi laibẹru ẹgan. Alafia ni fun awọn wọnni, T'a sa l'ami Kristi ninu ayé. Alafia ni f'ọmọ Ijọ yi, Ade ogo ni y'o jẹ ere rẹ. Ẹgbẹ na n kun, o si n tan kalẹ lọ, Lagbara Kristi yoo tan ka ayé. Agbara nla Kristi mbẹ f'ẹgbẹ yi, A o le subu larin igbi ayé. K'ẹni t'o n wa isubu Ẹgbẹ yi, Mọ p'o soro lati tapa sẹgun Gba t'ayé at'ogo rẹ ba dopin Ẹgbẹ yi yoo wa lai lọd'Oluwa. Kọ Haleluya s'Ọba Olore, F'Ẹgbẹ rere t'a gbe kalẹ s'ayé. AMIN

Hymn 818 – ALAFIA ni fun Ijo mimo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia