Hymn 806 – OLORUN agbaye, Owo ni f'Oruko re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN agbaye, Owo ni f'Oruko re" (C&S Hymn #806, Yoruba). ỌLỌRUN agbayé, Ọwọ ni f'Orukọ rẹ, Iwọ l'agbẹkẹle, lai ma jẹ…
ỌLỌRUN agbayé, Ọwọ ni f'Orukọ rẹ, Iwọ l'agbẹkẹle, lai ma jẹ k'oju ti wa, Bi ko se pe O kọ ‘le na, Osisẹ n se lasan, 'Wọ Alfa ati Omega, Ran iranwọ rẹ si wa. Ọba aiku, Airi, Mimọ ologo julọ, Ẹni ayérayé, t'o gunwa n'nu 'mọlẹ nla. Bi ko se pe O kọ ‘le na, Osisẹ n se lasan, 'Wọ Alfa ati Omega, Ran iranwọ rẹ si wa. L'ayé a ti l'ọrun, tani a ba fi we Ọ! Ẹlẹda, Alasẹ, Baba Olodumare. Bi ko se pe O kọ ‘le na, Osisẹ n se lasan, 'Wọ Alfa ati Omega, Ran iranwọ rẹ si wa. Iwọ l'o da ayé, ati ohun inu rẹ, O da awọn ọrun, ati gbogbo ogun wọn. Bi ko se pe O kọ ‘le na, Osisẹ n se lasan, 'Wọ Alfa ati Omega, Ran iranwọ rẹ si wa. Baba wa olore, at'oniyonu julọ, Ẹlẹru ni iyin, Ọlọrun alagbara, Bi ko se pe O kọ ‘le na, Osisẹ n se lasan, 'Wọ Alfa ati Omega, Ran iranwọ rẹ si wa. Mẹtalọkan lailai, Baba, Ọmọ oun Ẹmi, Ipilẹsẹ, Opin, Mimọ Awamaridi. Bi ko se pe O kọ ‘le na, Osisẹ n se lasan, 'Wọ Alfa ati Omega, Ran iranwọ rẹ si wa. Ogo f'orukọ rẹ, t'o ju gbogbo iyin lọ, Iwọ ni yin yẹ fun, tit'aye ainipẹkun. Bi ko se pe O kọ ‘le na, Osisẹ n se lasan, 'Wọ Alfa ati Omega, Ran iranwọ rẹ si wa. Amin Bi ko se pe O kọ ‘le na, Osisẹ n se lasan, 'Wọ Alfa ati Omega, Ran iranwọ rẹ si wa. APA KEJI Bi ko se pe O kọ ‘le na, Osisẹ n se lasan, 'Wọ Alfa ati Omega, Ran iranwọ rẹ si wa. ỌLỌRUN Agbayé, Iyin ni f'orukọ Rẹ, Iwọ l'a gbẹkẹle, Lai ma je k'oju ti wa. Bi ko se pe O kọ 'le na, Osisẹ n se lasan, 'Wọ Alfa ati Omega, Ran iranwọ rẹ si wa. Ọba aiku, airi, Mimọ Ologo julọ, Ipilẹsẹ Opin, O gunwa si Agbayé. Bi ko se pe O kọ 'le na, Osisẹ n se lasan, 'Wọ Alfa ati Omega, Ran iranwọ rẹ si wa. Jesu Olugbala, Iwọ l'o yan Séráfù, Lati bori ayé, A f'ogo f'orukọ rẹ. Bi ko se pe O kọ 'le na, Osisẹ n se lasan, 'Wọ Alfa ati Omega, Ran iranwọ rẹ si wa. Gbogbo Ẹgbẹ Seraf' T'o wa ni gbogbo ayé, Ẹ sin Olugbala, L'ẹmi ati l'otitọ. Bi ko se pe O kọ 'le na, Osisẹ n se lasan, 'Wọ Alfa ati Omega, Ran iranwọ rẹ si wa. Ọlọrun t'o yan Deborah, L'o yan Alakoso wa; Agbara igbani; Jọ fun Alakoso wa. Bi ko se pe O kọ 'le na, Osisẹ n se…
Hymn 806 – OLORUN agbaye, Owo ni f'Oruko re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia