Hymn 805 – OLUPAMO gbogbo eda | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUPAMO gbogbo eda" (C&S Hymn #805, Yoruba). OLUPAMỌ gbogbo ẹda, Ọba Asekan-maku, Awa fi malu ete wa, Rubọ ọpẹ si Ọ.…

Hymn 805 – OLUPAMO gbogbo eda | C&S Yoruba Hymnary
OLUPAMỌ gbogbo ẹda, Ọba Asekan-maku, Awa fi malu ete wa, Rubọ ọpẹ si Ọ. T'ọmọde at'agba dupẹ, F'abo Rẹ lori wa, Fun ikẹ ati igẹ Rẹ, Lori wa lat'esi. Ẹ bu s'ayọ ọmọ 'gun, Ati gbogbo ẹgbẹ, Ajọdun t'oni t'o ba wa, Lorilẹ alaye. Ẹlẹru, Niyin, a bẹ Ọ, Se wa l'eniyan Rẹ, K'a mase pada lọdọ Rẹ, K'a le sin Ọ dopin. Awa si mbẹbẹ siwaju, Nin' ọdun t'a wa yi, Fi ohun rere kari wa, S'ayé wa ni rere. Ọba amọna gbogb' ẹda, S'amọna wa dopin, Ma jẹ k'esu ba wa d'ẹgbọn; Ma jẹ k'a padanu. B'a ti n jọsin, t'a si n yin Ọ, L'aginju ayé yi, Se wa yẹ k'a tun le yin Ọ, Loke ọrun pẹlu. AMIN

Hymn 805 – OLUPAMO gbogbo eda | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia