Hymn 804 – DIDE tan imole, imole owuro | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "DIDE tan imole, imole owuro" (C&S Hymn #804, Yoruba). DIDE tan imọlẹ, imọlẹ owurọ, Jẹ ki ogo Oluwa yọ lara rẹ, Okunkun…
DIDE tan imọlẹ, imọlẹ owurọ, Jẹ ki ogo Oluwa yọ lara rẹ, Okunkun ẹsẹ ti bo ayé mọlẹ, Sugbọn awa ayanfẹ ti jade. Wa ọrẹ mi, ẹ wa k'a jọ yọ, Ẹ ke Hosannah s'Ọba Ogo, Apata ayérayé jọwọ mu 'leri sẹ. Awọn keferi y'o wa si 'mọlẹ Rẹ, Awọn Ọba y'o tẹriba fun Ọ, Gbe oju rẹ soke ki o wo yika, Siro 'rawọ, siro 'bukun loke. Wa ọrẹ mi, ẹ wa k'a jọ yọ, Ẹ ke Hosannah s'Ọba Ogo, Apata ayérayé jọwọ mu 'leri sẹ. Ọmọ alejo ni y'o mọ odi rẹ, Awọn Ọba yo' se 'ransẹ fun ọ Awọn ainilara rẹ y'o d'ofo, Y'o pa awọn ẹlẹgan lẹnu mọ. Wa ọrẹ mi, ẹ wa k'a jọ yọ, Ẹ ke Hosannah s'Ọba Ogo, Apata ayérayé jọwọ se isadi wa. Orun 'banujẹ ki y'o ran si wa mọ, Osupa ẹkun wa mbọ wa dopin, Ẹmi Jehovah y'o mu ọrọ mi se, Lati mu Ọba wa gunwa loke. Wa ọrẹ mi, ẹ wa k'a jọ yọ, Ẹ ke Hosannah s'Ọba Ogo, Apata ayérayé jọwọ se wa loke Rẹ. Mo se ọ ni wura asayan loni, Ẹmi agbara mi mbẹ lara rẹ, A bọ asọ eri kuro lara rẹ, Asọ ẹyẹ la fi dipo fun Ọ. Wa ọrẹ mi, ẹ wa k'a jọ yọ, Ẹ ke Hosannah s'Ọba Ogo, Apata ayérayé nikan l'ọpẹ yẹ fun loni. AMIN Wa ọrẹ mi, ẹ wa k'a jọ yọ, Ẹ ke Hosannah s'Ọba Ogo, Apata ayérayé nikan l'ọpẹ yẹ fun loni.
Hymn 804 – DIDE tan imole, imole owuro | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia