Hymn 803 – BABA Olorisun Ibukun gbogbo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "BABA Olorisun Ibukun gbogbo" (C&S Hymn #803, Yoruba). BABA Olorisun Ibukun gbogbo, Awa yin Ọ fun 'pade wa loni, Jọ…
BABA Olorisun Ibukun gbogbo, Awa yin Ọ fun 'pade wa loni, Jọ f'orisun ibukun Rẹ fun wa, Orisun 'bukun Rẹ ti ki gbẹ lai, Ọlọrun Abram, o d'ọwọ Rẹ, Nitori Jesu masai gbọ ẹbẹ wa. Sẹri 'bukun Rẹ s'ori gbogbo ẹgbẹ, At'Igbimọ l'ọkunrin, l'obinrin; Ẹgbẹ Akọrin ati gbogb' osisẹ, To mbẹ ninu Ẹgbẹ Séráfù yi; Ọlọrun Aaron, o dọwọ Rẹ, Di Ẹgbẹ Séráfù l'amure ododo. Jọ ma jẹki fitila Ẹgbẹ yi ku, Jọ mase jẹ k'ọta le ri gbe se, Jọ tun gbogbo ibajẹ inu rẹ se, Jẹ k'o gbilẹ n'nu 'fẹ oun 'wa mimọ, 'Wọ Ọba Sion, o dọwọ Re, Jo ma jẹ k'iyọ Ẹgbẹ wa yi d'obu. Bukun f'awọn ara ati ọrẹ wa, Ọmọ Ẹgbẹ at'awọn oworan Jẹ ko rọ wa; jẹ k'ile roju fun wa, K'a mase tori ara wa pose, Jehovah Salom, o dọwọ Rẹ, Mu ki 'paya lọ k'alafia pọ si. Siju anu Rẹ wo gbogbo Ẹgbẹ wa; Dawo pasan ibinu Rẹ duro, Darij' awọn ọta at'ẹlẹgan wa, Mu ọtẹ at'ija kuro fun wa, Jehovah Rufi, o dọwọ Rẹ, S'awotan arun to mba ilu wa ja. Baba, ma f'ebi kẹhin ayọ fun wa, K'a mase f'akisa pari asọ, Ma jẹ ka f'arun pari ara lile Ma jẹ ki awa ku sọwọ Esu, Ọlọrun Hagar, o dọwọ Rẹ, Pese itura fun wa ni ayé wa. Jọwọ f'ikẹ Rẹ kẹ awọn alaisan; F'adun si f'awọn t'ayé wọn koro, Fi ire kun gbogbo awọn ti ebi n pa; Jọ ma jẹ k'awọn ọmọ wa yanku, Jehovah Nissi, o dọwọ Rẹ, Masai j'Ọpagun fun gbogb' awọn Tirẹ. 'Wọ lo mu wa wa laye titi d'oni, Jẹ k'idasi wa jẹ fun Ogo Rẹ Lọwọ ewu at'ipalara gbogbo Jesu, masai fi isọ Rẹ sọ wa, Oyigiyigi, o dọwọ Rẹ, Pa mi mọ ki n mase gb'ọjọ ọlọjọ lọ. Lọjọ ti a o se idajọ ayé, T'awọn Angeli y'o wa kore fun Ọ; Gba wa, Jesu, gba wa ni ọjọ nla na, K'a wa le jẹ ninu ire nla na, Krist' Olugbala, o dọwọ Rẹ, Ma jẹ ki n tase ibukun rere na. AMIN
Hymn 803 – BABA Olorisun Ibukun gbogbo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia